31/10/2025
ÀÌSÀN ROPA ROSE (STROKE)
Mni igbagbo wipe gbogbo wa la mo nipa aisan eje riru ,?
nitiori oun gangan ni oga nkan ti o n fa ropa rose,
eleyi fi yewa wipe ti ako ba se amojuto blood pressure wa daadaa,
stroke lo ma gbeyin eni na.
Ropa rose je aisan,
kii se arun rara,
nitori a ko le ko ni ibi Kankan ayafi ti a ba jogun awon nkan to le fa,
aisan yi ti po ni lode oni daada
debi wipe opolopo awon eeyan lo ti ti ipase re lo si orun.
awon eyan tun so wipe jejere(cancer) na tun pa eeyan sugbon opolopo ni awon ti jejere n da lamu ti won tun ni eje riru leyi ti o ma n fa ropa rose
,elomiran a si tun ma ni ropa rose pelu jejere,
Ropa rose ni aisan kan ti o ma n wa ye nigbati lilo bibo eje ninu isan ara ba pakaso lati de inu opolo(brain) omo eda eniyan'
eleyi si le waye ni orisirisi ona,
fun apeere,
ti eje ko ba ti ri aaye lati de ibi ti opolo wa
eleyi ni o ma fa ki awon eya ara ti opolo na se alakoso re da ise sile,
nigba na ni a ma n ri wipe apa ti rọ,
ese ti ro
enu ti woọ
ahon ti lọ́
ati bebelo.
aisan yi tun le fa ki eeyan ma ranti nkankan mo,
awon isan ara na ma n da ise sile,
ibiti isoro ba rolu ninu opolo lo ma so iru nkan ti yio ma se alaisan na,
fun apeere,
ti o ba se wipe kekere ni apa ibiti opolo na ti ni arọ̀lù
opolo iru eeyan be ma n saba gbadun ,
sugbon ti arolu opolo yen ba po,
o seese ki eni na ma dide mo lailai.
bakan na ti aisan yi ba rolu eeyan,
opolopo igba ti o ba rolu apa osi ni o ma n fa iku nitori ibe ni okan wa,
eleyi yio si fa idiwo fun okan ati opolo lati ma sise ni asiko kanna,
aisan opolo ni roparose je,
Ti àìsàn yi ba ti n ba opolopo aaye nibi opolo ja,
Iru won ni owo abi ese won ma n gan pa ti ahon won na ma lo nitori eje dudu ti gba akoso aaye naa niyen.,
kosi eniti aisan yi ko le mu yala arugbo abi omo kekere,
aisan ropa rose je aisan ti o ma nsabaa pa eniti o ba mu nitori re ni awon oyinbo fi pe ni (TERMINAL DISEASE)
eeyan le dabo bo ara re ko ma ba ni aisan roparose yi.
kosi eniti ko le ni aisan na,
aisan yi le je afowofa,o si le je asasi
Aotun maa tẹsiwaju
Aoni fi àìsàn Logba o